Ìdì-Ẹ̀ka ní Ṣókí
Ìdì-Ẹ̀ka ní Ṣókí
Oṣù kìíní ọdún 2019 ni a ṣèdásílẹ̀ Ìdì-ẹ̀ka Ìgbógojá Ìmọ̀ Ilẹ̀ Áfíríkà, pẹ̀lú ìtílẹ́yìn Àjọ Ìgbógojá ti Ìjọba àpapọ̀ àti ti Ìpínlẹ̀ orílẹ̀ èdè Germany. Nípa ọ̀pọ̀ ìṣeyọrí Ẹ̀ka Ìmọ̀ nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ Áfíríkà ní Fáṣítì ìlú Bayreuth, Ìdì-ẹ̀ka Ìgbógojá Ìmọ̀ Ilẹ̀ Áfíríkà ṣèfilọ́lẹ̀ èròǹgbà gbòógì tí wọn pé àkọlé rẹ̀ ní “Ìṣàtúnwò Ìmọ̀ ilẹ̀ Áfíríkà”. Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, àwọn Olú Aṣèwádìí márùndínlọ́gbọ̀n ní wọ́n ń ṣèwádìí, àmọ́ ní báyìí, àwọn Aṣèwádìí ti lé ní ọgọ́rùn-ún láti kọ́ńtínẹ́ńtì mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn tí wọ́n ń ṣojú onírúurú ẹ̀ka ẹ̀kọ́, tí wọ́n sì ń pawọ́pọ̀ fún ìwádìí àjùmọ̀ṣe pẹ̀lú àwọn fásitì mìíràn ní ilẹ̀ Áfíríkà, orílẹ̀èdè Germany, Ilẹ̀ Europe, Asia, àti America.
Ó Ju Ìpànàdà Lọ
Òye tí a ní nípa Ìṣàtúnṣe/Ìṣàtúnwò sí Ìmọ̀ ile Áfíríkà dá lórí ìfojú tíọ́rì titun wo ọ̀nà àjùmọ̀ṣèwádìí lórí ọ̀rọ̀ Ilé Áfíríkà. Kì í ṣe láti Fáṣítì Bayreuth nìkan ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìdì-ẹ̀ka ti wá, bí kò ṣe láti àwọn alájọṣiṣẹ̀pọ̀ wa láti ilẹ̀ Áfíríkà àti láti ilẹ̀ mìíràn. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni wọ́n jọ ṣègbékalẹ̀ àwọn ìbéèrè ajẹmọ́wàádìí àti àwọn ìsẹ̀dá-tíọ́rì lórí àwọn ìwádìí láti oríṣi ẹ̀ka ẹ̀kọ́. Pàápàá jùlọ, àwọn ìwádìí tí a ṣe pẹlu àwọn Ẹ̀ka Ìdì Ìmọ̀ Áfíríkà (ACC) tí wọ́n wà ní Fáṣítì Joseph Ki-Zerbo (Burkina Faso), Fásítì Ìjọba Àpapọ̀ tó wà ní Èkó (Nigeria), Fásitì Moi (Kenya), Fásítì Rhodes (South Africa) pẹ̀lú ibi ìmọ̀ nípa ọ̀rọ̀ Áfíríkà àti Éṣíà tó wà ní Fásitì ìjọba àpapò tó wà ní Bahia (Brazil).
Ìpèsè Ààyè Ayíhunpadà fún Ìmọ̀ nípa Áfíríkà
Nípasẹ̀ Ẹ̀ka Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Áfíríkà ti Bayreuth, ìdì ẹ̀ka ń ṣètò jókòóṣèwdìí fún àwọn àgbà àti ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ aṣèwádìí, tí wọ́n ń pè wá kópa àti àwọn ìpè alágbàńlá-ayé tí à ń fi síta lóòrèkóòrè. Ilé ẹ̀kọ́ yìí a tún máa ṣe àkànṣe ètò fún ìkọ́ni àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀-gboyè PhD, pẹ̀lú ìgbàlejò ẹgbẹ́ àwọn ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ aṣèwádìí mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọn ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ ìwádìí tó jẹ́ mọ́ tí Cluster. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn tí wọ́n ń ṣe ẹ̀kọ́ PhD wọn lọ́wọ́ máa ń wáyé látipasẹ̀ Ẹ̀ka Ìmọ̀ Ìwádìí Ilẹ̀ Áfíríkà ti Bayreuth(BIGSAS), èyí tí wọ́n dá sílẹ̀ ní 2007.
Àǹfààní mìíràn tí BIGSAS tún máa ń ṣe ni láti pèsè àwọn apèwáṣèwádìí, àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde tí wọ́n lé ní igba ọ̀gọ́mọ̀ ọ̀mọ̀wé àti àwọn tó dáńgájíá.
Iwalewahaus, ìlúmọ̀ọ́ká ibùdó ìmọ̀ nípa iṣẹ́ àwòrán, tí wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1981, náà ń pèsè ààyè fún ìṣàfihàn onírúúrú iṣẹ́ ajẹmáwòrán, àkọọ́lẹ̀, iwádìí, àti àwọn ìmọ̀ àṣepọ̀ to dá lórí ilẹ̀ Áfíríkà. Gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Cluster, yálà, ní Bayreuth, Áfíríkà, tàbí ní ibòmíràn ní wọ́n jọ ń mọ ohun tí oníkálukú ń ṣe nípa Agbègbè Ìṣèwádí Ajẹmẹ́rọ (DRE). DRE yìí ń ṣàmúlo oríṣiríṣi dátà lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan, yálà àwọn aṣàmúlò iye tàbí àwọn aṣàmúlò ọ̀rọ̀, sí pèpéle tí ó ṣe é lò fún gbogbo èèyàn. Èyí sì fún ọ̀pọ̀ àwọn aṣèwádìí ní ànfàní láti ṣàfihàn ètò amúṣẹ́ṣe tí ó jẹ́ kí àwọn ohun tó díjú fojú, tàbí tí ó lọ́dìí òkòtó nípa ọ̀rọ̀ cluster fi ojú hàn kedere. Pẹ̀lú èròǹgbà láti ṣèfilọ́lẹ̀ àwọn ìmọ̀ ajẹmọ́ ẹ̀rọ abayélujára lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Cluster tún máa ń pèsè ètò oríòjorí àti ìdámọ̀ oríṣiríṣi àwọn ẹ̀dá alààyè nípa ètò ọ́ọ́fìsì Jẹ́ńdà ati Onírúurú (GDO), pẹ̀lú ètò àjọṣe àti ìkẹ́kọ̀ọ́ alárà-ọ̀tọ̀ (ICDL). Pẹ̀lú bí ọ́fíìsì GDO ṣe wà ní àárín ìṣèwádìí àti ṣíṣe kòkáárí, ọrọ ìdàgbàsókè àti ìfilọ́lẹ̀ àwọn ọ̀nà láti ṣàtúnṣe fún àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ, pẹ̀lú ìfagbára fún àwọn ọ̀nà ìgbàṣèwádìí nípasẹ̀ ìmọ̀ ẹ̀kọ́ alájọṣe.
Èrò àti Ọ̀nà Titun fún Ìwádìí
Àwọn èrò wa gan-an ni, ìfojúọ̀pọ̀woṣẹ́, ìfìbátanṣe, àti ìfèròinúṣe. À ń ṣàmúlò wọn láti le kápá àwọn ìbáṣepọ̀ọ onírúurú àti ìsopọ̀ tó dá lé ọ̀rọ̀ ìgbé ayé Áfíríkà àti Áfíríkà ẹ̀yìn odi. Ní Agódo Ìmọ̀, gbàgede ìmọ̀ cluster, a máa ń ṣe ìsopọ̀ àwọn tíọ́rì, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, àti àwọn ọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà ìgbàṣèwádìí, ìfọ̀rọ̀wérò, àti ìfikùnlukùn, a sì máa ń ṣàfihàn ètò iṣẹ́ titun àti ìdàgbàsókè tíọ́rì.
Àwọn orí kókó mẹ́fà, tí a ṣètò sí abala ìwádìí, pèsè ètò tó gúnmọ́ fún àwọn ìwádìí wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwádìí ló ń ṣàfojúsun àjọṣe ètò ẹ̀kọ́ oríṣiríṣi, ó sì tún ní í ṣe pẹ̀lú ìfọwọ́sòwọ́pọ̀ kíkún láàrin àwọn aṣèwádìí tó wà ní Bayreuth, àwọn tó wà ní Áfíríkà àti àwọn mìíràn tó wà káàkiri àgbáyé.